Èèwò̩ Yorùbá Nínú Ètò Ìs̩èlú Ilè̩ Nàìjíríà
(Èèwò̩ (Taboo) Yorùbá in Political Happenings of Nigeria)
Keywords:
Èèwọ̀ Yorùbá, Ètò Ìṣèlú, Òfin, Dídẹ́jàá, ÀwùjọAbstract
Èèwò̩ jé̩ ò̩kan pàtàkì nínú às̩à Yorùbá tí ó dàbí òfin tí e̩niké̩ni kò gbo̩dò̩ rú, tí àwo̩n o̩mo̩ Káàárò̩-o-ò-jíire ń s̩e àmúlò rè̩ láti ìgbà ìwásè̩ fún ààbò àti àlàáfíà tó péye láàrin ìlú. Bí ó tilè̩ jé̩ pé è̩sìn àjèjì, ò̩làjú àti ohun ìgbàlódé kò jé̩ kí ò̩pò̩lo̩pò̩ èèwò̩ Yorùbá fi e̩sè̩ múlè̩ ní àwùjo̩ òde òní, síbè̩síbè̩ àwo̩n o̩mo̩ Yorùbá tí èdè àti às̩à Yorùbá yé yékéyéké sì nígbàgbó̩ pé lóòrè-kóòrè ni èèwò̩ ń farahàn nínú ètò Ìs̩èlú àti Ìs̩èjo̩ba orílè̩ èdè Nàìjíríà èyí tí kò mú àlàáfíà bá ìlú. Détà fún is̩é̩ yii wá láti inú ò̩kan-ò-jò̩kan às̩àyàn ìwé tí ò̩rò̩ èèwò̩ àti ìs̩è̩lè̩ ìs̩èlú s̩odo sínú wo̩n pè̩lú ìfò̩rò̩wánilé̩nuwò onígbè̩fé̩ láti ò̩dò̩ àwo̩n abé̩nà ìwádìí méjì tí ó mo̩ tìfun-tè̩dò̩ èèwò̩ ilè̩ Yorùbá. Ète ìtúpalè̩ a-je̩-más̩à àti àwùjo̩ ni a lò fún ìtúpalè̩ bébà yìí nítorí pé nínú às̩à àwùjo̩ ni èèwò̩ wà àti pé àwùjo̩ ni ó ń s̩e àmúlò rè̩ gé̩gé̩ bí ó s̩e farahàn nínú ìs̩è̩lè̩ ètò ìs̩èlú àtè̩yìnwá ní orílè̩ èdè Nàìjíríà. Ìyànjú láti jé̩ kí á mo̩ ohun tí èèwò̩ jé̩, bí ó s̩e bè̩rè̩, àwo̩n ohun tó farahàn gé̩gé̩ bí èèwò̩ nínú Ìs̩èlú Ilè̩ Nàìjíríà, dídé̩jàá èèwò̩ àti ìjìyà tí ó wà fún e̩ni tó dé̩jàá èèwò̩ pè̩lú èròǹgbà pé, ó ye̩ kí àwùjo̩ òde òní s̩e àmúlò ìjì̀yà tó tó̩ fún dídé̩jàá èèwò̩ bí ó s̩e wà ní àtètèkó̩s̩e láìfi ò̩pò̩lo̩pò̩ àkókò s̩òfò tàbí ki o̩wó̩ òs̩èlú bo̩ ì̀wà ò̩daràn kí ìdájó̩ òdodo tó wáyé bí ti òde òní, ni ó s̩okùnfà pépà yìí. Ìmújáde èrò inú pépà yìí fi ìdí ò̩rò̩ múlè̩ pé èèwò̩ gan-an ni ó di òfin tí àwùjo̩ ń s̩àmúlò lóde òní, tí dídé̩jàá rè̩ túmò̩ sí rírú òfin èyi tí ó ye̩ kó ní ìjìyà lábé̩ òfin. Ó hàn gbangba pé lóòótó̩ ni ìjìyà wà fún arúfin nínú èèwò̩ láìfi àkókò s̩òfò, s̩ùgbó̩n lóde òní, nígbà mìíràn, arúfin kì í tètè gba ìdájó̩ è̩s̩è̩ tàbí kí ó má tilè̩ jìyà è̩s̩è̩ rárá nítorí pé àwo̩n alás̩e̩ lè ti fi o̩wó̩ òs̩èlú bò̩ ó̩. Ó ye̩ kí àwo̩n alás̩e̩ ìlú àti àwùjo̩ lápapò̩ padà sí e̩se̩ àárò̩ kí á sì s̩e àwòkó̩s̩e àwo̩n ò̩na tí Yorùbá ń gbà láyé o̩jó̩sí láti s̩e ìdájó̩ òdodo èyí tí kìí fi àkókò s̩òfò tàbí gbó̩mo̩ O̩bà fún Ò̩s̩un lórí adé̩jàá tàbí arúfin èèwò̩.